Ìjàpá je e̩ranko o̩ló̩gbó̩n è̩wé̩, anìkanjopó̩n, o̩ló̩gbó̩n àrekérekè àti wò̩nbílíkí-wò̩nbìà Ni o̩jó̩ kan, gbogbo e̩ranko inu igbo pète-pèrò lati lo̩ si àwùjo̩ àpèje̩ kan Olúkúlukù e̩ranko si s̩e òfin ti yoo mu ki àwo̩n e̩ranko ba le hu ìwà ti o bójúmu ni àwùjo̩ E̩kùn se òfin wipe; e̩niké̩ni ko gbó̩dò̩ sò̩rò̩ nibi oúnje , Kìnìún olóòlà ijù, ako̩mo̩nílà lai ni abe si so wipe oun ko fe ki awon eranko ja, agbonri si so wipe; oun yio gbe omi isanwo fun awon e̩ranko yooku, oàlukuluku so ofin ti won fe.
Ìjàpá si so fun awon eranko yooku wipe oruko oun ti pada o, ki enikeni maa se pe oun ni Ìjàpá mo nitori iyawo oun nikan lo ni ase lati maa pe oun ni Ìjàpá, ati wipe oruko ti oun maa je ni igboro ti oun mba jade si apeje ati apejo ni “Gbogboyín”
Nigbati won de àpèje̩ ti won pe won si, Ìjàpá ran gbogbo eranko leti ofin ti won se Awon eranko si ni beeni, ati wipe ko si eniti o maa ru awon ofin wonyi. Nigbati won de apeje, won si gbe oúnje was si agbo ti won joko si, eniti o gbe oúnje ohun de si so wipe “oúnje yi ti “Gbogboyín” nii o, Ìjàpá gba oúnje yi, o si beeresi jee, awon eranko yoku woju ara won, E̩kùn ni haba Ìjàpá oúnje yi fun gbogbo awa eranko ni, kiise fun iwo nikan o, Ìjàpá si wipe oúnje tiyin mbo e farabale.
Oúnje orisirisi miran tun de won so wipe oúnje yi wa fun “Gbogboyín”, Ìjàpá tun gbaa, awon eranko beeresi nkun, Ìjàpá ni e jowo e ranti ofin ti a se ki a to kuro ni ilu nitorina nko, a nilati tele ofin, bi won se gbe oúnje orisirisi ati oti orisirisi wa niyen, ti won ndaruko Gbogboyín ti Ìjàpá si nda je, nda mu. Ebi si npa awon eranko yooku, sugbon Ìjàpá nso fun won wipe ki won mu suuru wipe oúnje tiwon mbo lona. Bayi ni ebi pa gbogbo awon eranko, nigbati ara won ko gbaa mo ni Erin ba beeresi nba Kiniun ati E̩kùn wi wipe awon ni o gba igbakugba fun Ìjàpá. Ariwo yi po to bee gee ti awon gende mefa wole pelu Kòbókò ti won si so wipe won ni ebun nla fun “Gbogboyín” Ìjàpá jade wipe oun ni o ni ebun naa, bayi ni won se na Ìjàpá pelu Kòbóko, Ìjàpá to si ara o si tun ya igbe pelu.